caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Ash-Shura, ẹsẹ 13

Mecca · revelation order 62 · 42:13

شَرَعَ لَكُم مِّنَ ٱلدِّينِ مَا وَصَّىٰ بِهِۦ نُوحًا وَٱلَّذِىٓ أَوْحَيْنَآ إِلَيْكَ وَمَا وَصَّيْنَا بِهِۦٓ إِبْرَٰهِيمَ وَمُوسَىٰ وَعِيسَىٰٓ أَنْ أَقِيمُوا۟ ٱلدِّينَ وَلَا تَتَفَرَّقُوا۟ فِيهِ كَبُرَ عَلَى ٱلْمُشْرِكِينَ مَا تَدْعُوهُمْ إِلَيْهِ ٱللَّهُ يَجْتَبِىٓ إِلَيْهِ مَن يَشَآءُ وَيَهْدِىٓ إِلَيْهِ مَن يُنِيبُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Allāhu) ṣe ní òfin fún yín nínú ẹ̀sìn (’Islām) ohun tí Ó pa ní àṣẹ fún (Ànábì) Nūh àti èyí tí Ó fi ránṣẹ́ sí ọ, àti ohun tí A pa láṣẹ fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, (Ànábì) Mūsā àti (Ànábì) ‘Īsā pé, kí ẹ gbé ẹ̀sìn náà dúró. Kí ẹ sì má ṣe pín sí ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú rẹ̀. Wàhálà l’ó jẹ́ fún àwọn ọ̀ṣẹbọ nípa n̄ǹkan tí ò ń pè wọ́n sí (níbi mímú Allāhu ní ọ̀kan ṣoṣo). Allāhu l’Ó ń ṣẹ̀ṣà ẹni tí Ó bá fẹ́ sínú ẹ̀sìn Rẹ̀ (tí ò ń pè wọ́n sí). Ó sì ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó bá ń ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ (nípasẹ̀ ìronúpìwàdà).
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70