وَمِنْ ءَايَٰتِهِۦٓ أَنَّكَ تَرَى ٱلْأَرْضَ خَٰشِعَةً فَإِذَآ أَنزَلْنَا عَلَيْهَا ٱلْمَآءَ ٱهْتَزَّتْ وَرَبَتْ إِنَّ ٱلَّذِىٓ أَحْيَاهَا لَمُحْىِ ٱلْمَوْتَىٰٓ إِنَّهُۥ عَلَىٰ كُلِّ شَىْءٍ قَدِيرٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNínú àwọn àmì Rẹ̀ tún ni pé dájúdájú ìwọ yóò rí ilẹ̀ ní asálẹ̀. Nígbà tí A bá sì sọ omi kalẹ̀ lé e lórí, ó máa rúra wá, ó sì máa ga (fún híhu irúgbìn jáde). Dájúdájú Ẹni tí Ó talẹ̀ jí, Òun mà ni Ẹni tí Ó máa sọ àwọn òkú di alààyè. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.