أَلَآ إِنَّ لِلَّهِ مَا فِى ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ قَدْ يَعْلَمُ مَآ أَنتُمْ عَلَيْهِ وَيَوْمَ يُرْجَعُونَ إِلَيْهِ فَيُنَبِّئُهُم بِمَا عَمِلُوا۟ وَٱللَّهُ بِكُلِّ شَىْءٍ عَلِيمٌۢ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelGbọ́! Dájúdájú ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó sì ti mọ ohun tí ẹ wà lórí rẹ̀. (Rántí) ọjọ́ tí wọn yó dá wọn padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, Ó sì máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.