فَإِن لَّمْ تَجِدُوا۟ فِيهَآ أَحَدًا فَلَا تَدْخُلُوهَا حَتَّىٰ يُؤْذَنَ لَكُمْ وَإِن قِيلَ لَكُمُ ٱرْجِعُوا۟ فَٱرْجِعُوا۟ هُوَ أَزْكَىٰ لَكُمْ وَٱللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ عَلِيمٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí ẹ ò bá sì bá ẹnì kan kan nínú ilé náà, ẹ má ṣe wọ inú rẹ̀ títí wọn yóò fi yọ̀ǹda fún yín. Tí wọ́n bá sì sọ fún yín pé kí ẹ padà, nítorí náà ẹ padà. Òhun ló fọ̀ yín mọ́ jùlọ. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.