أَوْ كَصَيِّبٍ مِّنَ ٱلسَّمَآءِ فِيهِ ظُلُمَٰتٌ وَرَعْدٌ وَبَرْقٌ يَجْعَلُونَ أَصَٰبِعَهُمْ فِىٓ ءَاذَانِهِم مِّنَ ٱلصَّوَٰعِقِ حَذَرَ ٱلْمَوْتِ وَٱللَّهُ مُحِيطٌۢ بِٱلْكَٰفِرِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTàbí (àpèjúwe wọn) dà bí òjò ńlá tí ń rọ̀ láti sánmọ̀. Ó mú àwọn òkùnkùn, àrá sísán àti mọ̀nàmọ́ná lọ́wọ́. Wọ́n ń fi ìka wọn sínú etí wọn nítorí àwọn iná láti ojú sánmọ̀ fún ìbẹ̀rù ikú. Allāhu sì yí àwọn aláìgbàgbọ́ ká.