caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Ibrahim, ẹsẹ 10

Mecca · revelation order 72 · 14:10

قَالَتْ رُسُلُهُمْ أَفِى ٱللَّهِ شَكٌّ فَاطِرِ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ يَدْعُوكُمْ لِيَغْفِرَ لَكُم مِّن ذُنُوبِكُمْ وَيُؤَخِّرَكُمْ إِلَىٰٓ أَجَلٍ مُّسَمًّى قَالُوٓا۟ إِنْ أَنتُمْ إِلَّا بَشَرٌ مِّثْلُنَا تُرِيدُونَ أَن تَصُدُّونَا عَمَّا كَانَ يَعْبُدُ ءَابَآؤُنَا فَأْتُونَا بِسُلْطَٰنٍ مُّبِينٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn Òjíṣẹ́ wọn sọ pé: “Ṣé iyèméjì kan ń bẹ níbi (bíbẹ) Allāhu, Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Ó ń pè yín nítorí kí Ó lè forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín àti nítorí kí Ó lè lọ yín lára di gbèdéke àkókò kan.” Wọ́n wí pé: “Ẹ̀yin kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú wa. Ẹ̀yin sì fẹ́ ṣẹ́ wa lórí kúrò níbi n̄ǹkan tí àwọn bàbá wa ń jọ́sìn fún. Nítorí náà, ẹ fún wa ní ẹ̀rí pọ́nńbélé.”
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70