فَلَمَّا ذَهَبُوا۟ بِهِۦ وَأَجْمَعُوٓا۟ أَن يَجْعَلُوهُ فِى غَيَٰبَتِ ٱلْجُبِّ وَأَوْحَيْنَآ إِلَيْهِ لَتُنَبِّئَنَّهُم بِأَمْرِهِمْ هَٰذَا وَهُمْ لَا يَشْعُرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí wọ́n mú un lọ tán, wọ́n panupọ̀ pé kí àwọn jù ú sí ìsàlẹ̀ẹ̀sàlẹ̀ kànǹga. À si fí ìmísí ránṣẹ́ sí Yūsuf (níbẹ̀) pé: “Dájúdájú ìwọ yóò fún wọn ní ìró nípa ọ̀rọ̀ wọn yìí nígbà tí wọn kò níí fura.”