إِنَّمَا يَعْمُرُ مَسَٰجِدَ ٱللَّهِ مَنْ ءَامَنَ بِٱللَّهِ وَٱلْيَوْمِ ٱلْـَٔاخِرِ وَأَقَامَ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتَى ٱلزَّكَوٰةَ وَلَمْ يَخْشَ إِلَّا ٱللَّهَ فَعَسَىٰٓ أُو۟لَٰٓئِكَ أَن يَكُونُوا۟ مِنَ ٱلْمُهْتَدِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸni tí yóò máa ṣàmójútó àwọn mọ́sálásí Allāhu ni ẹni tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tó sì ń kírun, tó ń yọ Zakāh, kò sì páyà (òrìṣà kan) lẹ́yìn Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n kúkú wà nínú àwọn olùmọ̀nà.