وَلِلَّهِ ٱلْأَسْمَآءُ ٱلْحُسْنَىٰ فَٱدْعُوهُ بِهَا وَذَرُوا۟ ٱلَّذِينَ يُلْحِدُونَ فِىٓ أَسْمَٰٓئِهِۦ سَيُجْزَوْنَ مَا كَانُوا۟ يَعْمَلُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTi Allāhu ni àwọn orúkọ tó dára jùlọ. Nítorí náà, ẹ fi pè É. Kí ẹ sì pa àwọn tó ń darí àwọn orúkọ Rẹ̀ kọ ọ̀nà òdì tì.[1] A óò san wọ́n ní ẹ̀san ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.