caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà At-Tahrim, ẹsẹ 10

Medina · revelation order 107 · 66:10

ضَرَبَ ٱللَّهُ مَثَلًا لِّلَّذِينَ كَفَرُوا۟ ٱمْرَأَتَ نُوحٍ وَٱمْرَأَتَ لُوطٍ كَانَتَا تَحْتَ عَبْدَيْنِ مِنْ عِبَادِنَا صَٰلِحَيْنِ فَخَانَتَاهُمَا فَلَمْ يُغْنِيَا عَنْهُمَا مِنَ ٱللَّهِ شَيْـًٔا وَقِيلَ ٱدْخُلَا ٱلنَّارَ مَعَ ٱلدَّٰخِلِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu fi ìyàwó (Ànábì) Nūh àti ìyàwó (Ànábì) Lūt ṣe àpẹ̀ẹrẹ fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́. Àwọn méjèèjì wà lábẹ́ ẹrúsìn méjì rere nínú àwọn ẹrúsìn Wa. Àwọn (obìnrin) méjèèjì sì jàǹbá àwọn ọkọ wọn. Àwọn ọkọ wọn kò sì fi kiní kan rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ lọ́dọ̀ Allāhu. A ó sì sọ fún àwọn obìnrin méjèèjì pé: “Ẹ wọ inú Iná pẹ̀lú àwọn olùwọlé (sínú Iná).”
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70