يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ إِنَّا خَلَقْنَٰكُم مِّن ذَكَرٍ وَأُنثَىٰ وَجَعَلْنَٰكُمْ شُعُوبًا وَقَبَآئِلَ لِتَعَارَفُوٓا۟ إِنَّ أَكْرَمَكُمْ عِندَ ٱللَّهِ أَتْقَىٰكُمْ إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمٌ خَبِيرٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀yin ènìyàn, dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá yín láti ara ọkùnrin àti obìnrin. A sì ṣe yín ní orílẹ̀-èdè orílẹ̀-èdè àti ìran-ìran nítorí kí ẹ lè dára yín mọ̀. Dájúdájú alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ nínú yín lọ́dọ̀ Allāhu ni ẹni tó bẹ̀rù (Rẹ̀) jùlọ. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀, Alámọ̀tán.