وَتَرَىٰهُمْ يُعْرَضُونَ عَلَيْهَا خَٰشِعِينَ مِنَ ٱلذُّلِّ يَنظُرُونَ مِن طَرْفٍ خَفِىٍّ وَقَالَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓا۟ إِنَّ ٱلْخَٰسِرِينَ ٱلَّذِينَ خَسِرُوٓا۟ أَنفُسَهُمْ وَأَهْلِيهِمْ يَوْمَ ٱلْقِيَٰمَةِ أَلَآ إِنَّ ٱلظَّٰلِمِينَ فِى عَذَابٍ مُّقِيمٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelO sì máa rí wọn tí A máa kó wọn lọ sínú Iná; wọn yóò palọ́lọ́ láti ara ìyẹpẹrẹ, wọn yó si máa wò fín-ín-fín. Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo sì máa sọ pé: “Dájúdájú àwọn ẹni òfò ni àwọn tó ṣe ẹ̀mí ara wọn àti ara ilé wọn ní òfò ní Ọjọ́ Àjíǹde.” Kíyè sí i, dájúdájú àwọn alábòsí yóò wà nínú ìyà gbére.