وَلَمَّا رَءَا ٱلْمُؤْمِنُونَ ٱلْأَحْزَابَ قَالُوا۟ هَٰذَا مَا وَعَدَنَا ٱللَّهُ وَرَسُولُهُۥ وَصَدَقَ ٱللَّهُ وَرَسُولُهُۥ وَمَا زَادَهُمْ إِلَّآ إِيمَٰنًا وَتَسْلِيمًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí àwọn onígbàgbọ́ òdodo rí àwọn ọmọ ogun oníjọ, wọ́n sọ pé: “Èyí ni ohun tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ṣe ní àdéhùn fún wa.[1] Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ti sọ òdodo ọ̀rọ̀.” (Rírí wọn) kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe (àlékún) ìgbàgbọ́ òdodo àti ìjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀ (fún àṣẹ Allāhu).