فَأَصْبَحَ فِى ٱلْمَدِينَةِ خَآئِفًا يَتَرَقَّبُ فَإِذَا ٱلَّذِى ٱسْتَنصَرَهُۥ بِٱلْأَمْسِ يَسْتَصْرِخُهُۥ قَالَ لَهُۥ مُوسَىٰٓ إِنَّكَ لَغَوِىٌّ مُّبِينٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ó di ẹni tó ń bẹ̀rù nínú ìlú, ó sì ń retí (ẹ̀hónú ìran Fir‘aon). Nígbà náà ni ẹni tí ó wá ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ ní àná tún ń lọgun rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀. Mūsā sọ fún un pé: “Dájúdájú ìwọ ni olùṣìnà pọ́nńbélé.”