caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà An-Noor, ẹsẹ 21

Medina · revelation order 102 · 24:21

يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ لَا تَتَّبِعُوا۟ خُطُوَٰتِ ٱلشَّيْطَٰنِ وَمَن يَتَّبِعْ خُطُوَٰتِ ٱلشَّيْطَٰنِ فَإِنَّهُۥ يَأْمُرُ بِٱلْفَحْشَآءِ وَٱلْمُنكَرِ وَلَوْلَا فَضْلُ ٱللَّهِ عَلَيْكُمْ وَرَحْمَتُهُۥ مَا زَكَىٰ مِنكُم مِّنْ أَحَدٍ أَبَدًا وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ يُزَكِّى مَن يَشَآءُ وَٱللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe tẹ̀lé àwọn ojú-ẹsẹ̀ aṣ-ṣaetọ̄n. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì tẹ̀lé àwọn ojú-ẹsẹ̀ aṣ-ṣaetọ̄n, dájúdájú (aṣ-ṣaetọ̄n) yóò pàṣẹ ìwà ìbàjẹ́ àti aburú (fún un). Tí kì í bá ṣe oore àjùlọ Allāhu àti ìkẹ́ Rẹ̀ lórí yín ni, ẹnì kan kan ìbá tí mọ́ nínú yín láéláé. Ṣùgbọ́n Allāhu ń ṣàfọ̀mọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70