أَلَمْ تَرَ أَنَّ ٱللَّهَ سَخَّرَ لَكُم مَّا فِى ٱلْأَرْضِ وَٱلْفُلْكَ تَجْرِى فِى ٱلْبَحْرِ بِأَمْرِهِۦ وَيُمْسِكُ ٱلسَّمَآءَ أَن تَقَعَ عَلَى ٱلْأَرْضِ إِلَّا بِإِذْنِهِۦٓ إِنَّ ٱللَّهَ بِٱلنَّاسِ لَرَءُوفٌ رَّحِيمٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu rọ ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ fún yín, àti ọkọ̀ ojú-omi tó ń rìn nínú agbami odò pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀, Ó ń mú sánmọ̀ dání tí kò fi jábọ́ sórí ilẹ̀ àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀? Dájúdájú Allāhu mà ni Aláàánú, Oníkẹ̀ẹ́ fún àwọn ènìyàn.