وَإِذْ بَوَّأْنَا لِإِبْرَٰهِيمَ مَكَانَ ٱلْبَيْتِ أَن لَّا تُشْرِكْ بِى شَيْـًٔا وَطَهِّرْ بَيْتِىَ لِلطَّآئِفِينَ وَٱلْقَآئِمِينَ وَٱلرُّكَّعِ ٱلسُّجُودِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ẹ rántí) nígbà tí A ṣàfi hàn àyè ilé náà fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm (A sì pa á láṣẹ) pé o ò gbọdọ̀ sọ kiní kan di akẹgbẹ́ fún Mi. Àti pé kí o ṣe ilé Mi ní mímọ́ fún àwọn olùyípo rẹ̀, olùkírun, olùdáwọ́tẹ-orúnkún àti olùforíkanlẹ̀.