caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Taa-Haa, ẹsẹ 40

Mecca · revelation order 45 · 20:40

إِذْ تَمْشِىٓ أُخْتُكَ فَتَقُولُ هَلْ أَدُلُّكُمْ عَلَىٰ مَن يَكْفُلُهُۥ فَرَجَعْنَٰكَ إِلَىٰٓ أُمِّكَ كَىْ تَقَرَّ عَيْنُهَا وَلَا تَحْزَنَ وَقَتَلْتَ نَفْسًا فَنَجَّيْنَٰكَ مِنَ ٱلْغَمِّ وَفَتَنَّٰكَ فُتُونًا فَلَبِثْتَ سِنِينَ فِىٓ أَهْلِ مَدْيَنَ ثُمَّ جِئْتَ عَلَىٰ قَدَرٍ يَٰمُوسَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Rántí) nígbà tí arábìnrin rẹ ń rìn lọ, ó sì ń sọ pé: “Ṣé kí n̄g júwe yín sí ẹni tí ó máa gbà á tọ́?” A sì dá ọ padà sọ́dọ̀ ìyá rẹ nítorí kí ó lè ní ìtutù ojú, àti pé kí ò má baà banújẹ́. Àti pé o pa ẹ̀mí ẹnì kan. A sì mú ọ kúrò nínú ìbànújẹ́. A tún mú àwọn àdánwò kan bá ọ. O tún lo àwọn ọdún kan lọ́dọ̀ àwọn ará Mọdyan. Lẹ́yìn náà, o dé (ní àkókò) tí ó ti wà nínú kádàrá, Mūsā.
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70