هُوَ ٱلَّذِى خَلَقَ لَكُم مَّا فِى ٱلْأَرْضِ جَمِيعًا ثُمَّ ٱسْتَوَىٰٓ إِلَى ٱلسَّمَآءِ فَسَوَّىٰهُنَّ سَبْعَ سَمَٰوَٰتٍ وَهُوَ بِكُلِّ شَىْءٍ عَلِيمٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÒun ni Ẹni tí Ó dá ohunkóhun tó wà lórí ilẹ̀ fún yín pátápátá. Lẹ́yìn náà, Ó dojúkọ (dídá) sánmọ̀, Ó sì ṣe wọ́n tógún régé sí sánmọ̀ méje. Òun sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.