إِذْ تَبَرَّأَ ٱلَّذِينَ ٱتُّبِعُوا۟ مِنَ ٱلَّذِينَ ٱتَّبَعُوا۟ وَرَأَوُا۟ ٱلْعَذَابَ وَتَقَطَّعَتْ بِهِمُ ٱلْأَسْبَابُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Rántí) nígbà tí àwọn tí wọ́n tẹ̀lé (ìyẹn àwọn aṣíwájú kèfèrí) bá yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ àwọn tó tẹ̀lé wọn; (nígbà tí) wọ́n bá fojú rí Ìyà, tí ohun tó so wọ́n pọ̀ sì já pátápátá.