ٱلَّذِينَ ءَاتَيْنَٰهُمُ ٱلْكِتَٰبَ يَعْرِفُونَهُۥ كَمَا يَعْرِفُونَ أَبْنَآءَهُمْ وَإِنَّ فَرِيقًا مِّنْهُمْ لَيَكْتُمُونَ ٱلْحَقَّ وَهُمْ يَعْلَمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn tí A fún ní Tírà, wọ́n mọ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe mọ àwọn ọmọ wọn. Dájúdájú àwọn ìjọ kan wà nínú wọn tí wọ́n kúkú ń fi òdodo pamọ́, wọ́n sì mọ̀.