أُو۟لَٰٓئِكَ لَهُمْ جَنَّٰتُ عَدْنٍ تَجْرِى مِن تَحْتِهِمُ ٱلْأَنْهَٰرُ يُحَلَّوْنَ فِيهَا مِنْ أَسَاوِرَ مِن ذَهَبٍ وَيَلْبَسُونَ ثِيَابًا خُضْرًا مِّن سُندُسٍ وَإِسْتَبْرَقٍ مُّتَّكِـِٔينَ فِيهَا عَلَى ٱلْأَرَآئِكِ نِعْمَ ٱلثَّوَابُ وَحَسُنَتْ مُرْتَفَقًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn wọ̀nyẹn, tiwọn ni àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra ‘Adn, tí àwọn odò yóò máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ wọn. Wọn máa ṣe wọ́n ní ọ̀ṣọ́ nínú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn n̄ǹkan ọwọ́ látara wúrà. Wọn yóò máa wọ aṣọ àrán aláwọ̀ ewéko (èyí tí ó) fẹ́lẹ́ àti (èyí tí) ó nípọn. Wọn yó sì máa rọ̀gbọ̀kú lórí ibùsùn ọlá nínú (Ọgbà Ìdẹ̀ra). Ẹ̀san náà dára. Ó sì dára ní ibùkójọ.