caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà At-Tawba, ẹsẹ 70

Medina · revelation order 113 · 9:70

أَلَمْ يَأْتِهِمْ نَبَأُ ٱلَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ قَوْمِ نُوحٍ وَعَادٍ وَثَمُودَ وَقَوْمِ إِبْرَٰهِيمَ وَأَصْحَٰبِ مَدْيَنَ وَٱلْمُؤْتَفِكَٰتِ أَتَتْهُمْ رُسُلُهُم بِٱلْبَيِّنَٰتِ فَمَا كَانَ ٱللَّهُ لِيَظْلِمَهُمْ وَلَٰكِن كَانُوٓا۟ أَنفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé ìròyìn àwọn tó ṣíwájú wọn kò tí ì dé bá wọn ni? (Ìròyìn) ìjọ (Ànábì) Nūh, ìran ‘Ād, ìran Thamūd, ìjọ (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, àwọn ará Mọdyan àti àwọn ìlú tí A dojú rẹ̀ bolẹ̀ (ìjọ Ànábì Lūt); àwọn Òjíṣẹ́ wọn wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú. Nítorí náà, Allāhu kò ṣe àbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ṣàbòsí sí.
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70