وَإِذْ يُرِيكُمُوهُمْ إِذِ ٱلْتَقَيْتُمْ فِىٓ أَعْيُنِكُمْ قَلِيلًا وَيُقَلِّلُكُمْ فِىٓ أَعْيُنِهِمْ لِيَقْضِىَ ٱللَّهُ أَمْرًا كَانَ مَفْعُولًا وَإِلَى ٱللَّهِ تُرْجَعُ ٱلْأُمُورُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Rántí) nígbà tí Ó ń fi wọ́n hàn yín pé wọ́n kéré lójú yín - nígbà tí ẹ pàdé (lójú ogun) - Ó sì mú ẹ̀yin náà kéré lójú tiwọn náà, nítorí kí Allāhu lè mú ọ̀rọ̀ kan tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹ wá sí ìmúṣẹ. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí.