فَلَمَّا كَشَفْنَا عَنْهُمُ ٱلرِّجْزَ إِلَىٰٓ أَجَلٍ هُم بَٰلِغُوهُ إِذَا هُمْ يَنكُثُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí A gbé ìyà náà kúrò fún wọn fún àkókò kan tí wọn yóò lò (nínú ìṣẹ̀mí wọn), nígbà náà ni wọ́n tún ń yẹ àdéhùn.