إِنَّ ٱلَّذِينَ يُجَٰدِلُونَ فِىٓ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ بِغَيْرِ سُلْطَٰنٍ أَتَىٰهُمْ إِن فِى صُدُورِهِمْ إِلَّا كِبْرٌ مَّا هُم بِبَٰلِغِيهِ فَٱسْتَعِذْ بِٱللَّهِ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلْبَصِيرُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn tó ń jiyàn nípa àwọn āyah Allāhu láìní ẹrí kan (lọ́wọ́) tí ó wá bá wọn (láti ọ̀dọ̀ Allāhu), kò sí kiní kan nínú igbá-àyà wọn àyàfi ọkàn-gíga. Wọn kò sì lè dé ibi gíga (pẹ̀lú ọkàn gíga). Nítorí náà, sá di Allāhu. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Olùríran.