يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ ٱذْكُرُوا۟ نِعْمَةَ ٱللَّهِ عَلَيْكُمْ إِذْ جَآءَتْكُمْ جُنُودٌ فَأَرْسَلْنَا عَلَيْهِمْ رِيحًا وَجُنُودًا لَّمْ تَرَوْهَا وَكَانَ ٱللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ rántí ìdẹ̀ra Allāhu lórí yín, nígbà tí àwọn ọmọ ogun (oníjọ) dé ba yín. A sì rán atẹ́gùn àti àwọn ọmọ ogun tí ẹ kò fójú rí sí wọn. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.[1]