وَلَئِن سَأَلْتَهُم مَّن نَّزَّلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءً فَأَحْيَا بِهِ ٱلْأَرْضَ مِنۢ بَعْدِ مَوْتِهَا لَيَقُولُنَّ ٱللَّهُ قُلِ ٱلْحَمْدُ لِلَّهِ بَلْ أَكْثَرُهُمْ لَا يَعْقِلُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí o bá bi wọ́n léèrè pé: “Ta ni Ó sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀, tí Ó fi ta ilẹ̀ jí lẹ́yìn tí ó ti kú?”, dájúdájú wọ́n á wí pé: “Allāhu ni.” Sọ pé: “Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò ṣe làákàyè.”