قُلْ كَفَىٰ بِٱللَّهِ بَيْنِى وَبَيْنَكُمْ شَهِيدًا يَعْلَمُ مَا فِى ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ بِٱلْبَٰطِلِ وَكَفَرُوا۟ بِٱللَّهِ أُو۟لَٰٓئِكَ هُمُ ٱلْخَٰسِرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ pé: “Allāhu tó ní Ẹlẹ́rìí láààrin èmi àti ẹ̀yin. Ó mọ ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àwọn tó gba irọ́ (òrìṣà) gbọ́, tí wọ́n sì ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu; àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni ẹni òfò.