وَمَآ أَرْسَلْنَا مِن رَّسُولٍ إِلَّا بِلِسَانِ قَوْمِهِۦ لِيُبَيِّنَ لَهُمْ فَيُضِلُّ ٱللَّهُ مَن يَشَآءُ وَيَهْدِى مَن يَشَآءُ وَهُوَ ٱلْعَزِيزُ ٱلْحَكِيمُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA kò rán Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ àfi pẹ̀lú èdè[1] àwọn ènìyàn rẹ̀² nítorí kí ó lè ṣàlàyé (ẹ̀sìn) fún wọn. Nígbà náà, Allāhu yóò ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà. Ó sì máa tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sọ́nà; Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.