وَأَمَّا ٱلَّذِينَ سُعِدُوا۟ فَفِى ٱلْجَنَّةِ خَٰلِدِينَ فِيهَا مَا دَامَتِ ٱلسَّمَٰوَٰتُ وَٱلْأَرْضُ إِلَّا مَا شَآءَ رَبُّكَ عَطَآءً غَيْرَ مَجْذُوذٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNí ti àwọn tí A bá ṣe ní olórí-ire, wọ́n máa wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ ní òdíwọ̀n ìgbà tí àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fi ń bẹ[1], àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́.² (Ọgbà Ìdẹ̀ra jẹ́) ọrẹ àìlópin.