ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبُّكُمْ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ خَٰلِقُ كُلِّ شَىْءٍ فَٱعْبُدُوهُ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَىْءٍ وَكِيلٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌyẹn ni Allāhu, Olúwa yín; kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Ẹlẹ́dàá gbogbo n̄ǹkan. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Òun sì ni Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan.