وَيَقُولُونَ ءَامَنَّا بِٱللَّهِ وَبِٱلرَّسُولِ وَأَطَعْنَا ثُمَّ يَتَوَلَّىٰ فَرِيقٌ مِّنْهُم مِّنۢ بَعْدِ ذَٰلِكَ وَمَآ أُو۟لَٰٓئِكَ بِٱلْمُؤْمِنِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n ń wí pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ náà. A sì tẹ̀lé (àṣẹ wọn).” Lẹ́yìn náà, igun kan nínú wọn ń pẹ̀yìndà lẹ́yìn ìyẹn. Àwọn wọ̀nyẹn kì í ṣe onígbàgbọ́ òdodo.